14 “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró.Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí,mo ṣunkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
15 Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahorotí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù;Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣùn ó sì gbẹ àwọn adágún.
16 Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,ní ipa-ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájúu wọnàti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
17 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
18 “Gbọ́, ìwọ adití,wòó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!
19 Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?
20 Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkankan.”