2 Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe ṣókè,tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ ṣókè ní òpópónà.
3 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́àti òwú-àtùpà tí ń jó tan an lọlòun kì yóò fẹ́ pa.Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;
4 Òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sìtítí tí yóò fi fi ìdájọ́ mulẹ̀ ní ayé.Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètíi wọn sí.”
5 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wíẸni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n ṣóde,tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú un wọn,Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémíàti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú un rẹ̀:
6 “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo;Èmi yóò di ọwọ́ọ̀ rẹ mú.Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyànàti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
7 láti la àwọn ojú tí ó fọ́,láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbúàti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀nàwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
8 “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràntàbí ìyìn mi fún ère-òrìṣà.