Àìsáyà 44:15-21 BMY

15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kíara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tíó sì ń sìn ín;ó yá ère, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.

16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;lóríi rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”

17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;ó forí balẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”

18 Wọn kò mọ nǹkankan, nǹkankan kò yé wọn;a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkankan;bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkankan.

19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òyeláti sọ wí pé,“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kannínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”

20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ̀tàn ni ó sì í lọ́nà;òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”

21 “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, Ìwọ Jákọ́bùnítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì.Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,Èmi Ísírẹ́lì, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.