Àìsáyà 44:9-15 BMY

9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́kò jámọ́ nǹkankan.Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn.

10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójú tì;àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sìfi ìdúró wọn hàn;gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.

12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;ó fi òòlù ya ère kan,ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́nó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀,Ó tún fi ṣísẹ́lì họ ọ́ jádeó tún fi kọ́ḿpáásì ṣe àmì sí i.Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàngẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.

14 Ó gé igi kédárì lulẹ̀,tàbí bóyá ó mú Ṣípírẹ́sì tàbí óákù.Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó,ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.

15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kíara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tíó sì ń sìn ín;ó yá ère, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.