22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé;nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì sí ẹlòmìíràn.
23 Nípa èmi tìkálára mi ni mo ti búra,ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lúu gbogbo ipá miọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́:Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan niòdodo àti agbára wà.’ ”Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójú tì wọn.
25 Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Ísírẹ́lìni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.