Àìsáyà 5:23-29 BMY

23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.

24 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àkékù koríko runàti bí koríko ṣe relẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹràtí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

25 Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ ṣókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.Àwọn òkè mì tìtì,àwọn òkú sì dàbí ààtàn lójú òpópó ọ̀nà.Pẹ̀lúu gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíí kúrò,ọ̀wọ́ rẹ̀ sì gbé ṣókè síbẹ̀.

26 Ó gbé ọ̀págun ṣókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà-réré,Ó súfèé sí àwọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.Àwọn rè é, wọ́n ti sáré

27 Kò rẹ ẹnìkankan nínú wọn, tàbí kí ó kọṣẹ̀.Ẹnikẹ́ni ò tòògbé tàbí sùn;Ìgbànú ẹnìkankan ò dẹ̀ ní ìbàdí i rẹ̀,okùn sálúbàtà kan ò já.

28 Àwọn ọfà wọn múná,gbogbo ọrun wọn sì lò;pátakò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta-akọàwọn àgbá kẹ̀kẹ̀ wọn sì dàbí ìjì líle.

29 Bíbú wọn dàbí tí kìnnìhún,wọ́n bú bí ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìhún,wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹranànjẹ wọn mútí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.