1 “Kọrin, Ìwọ obìnrin àgàn,ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;búsí orin, ẹ hó fún ayọ̀,ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoroju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”ni Olúwa wí.
2 Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,má ṣe dá a dúró;sọ okùn rẹ di gígùn,mú òpo rẹ lágbára sí i.
3 Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn-ún àti sí òsì;ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀ èdè,wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
4 “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwee rẹÌwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìwà-rópó rẹ mọ́.
5 Nítorí Ẹlẹ́dáà rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni Olùràpadà rẹ;a sì pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
6 Olúwa yóò pè ọ́ padàà fi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀tí a sì bà lọ́kàn jẹ́obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,tí a sì wá já kulẹ̀” ni Olúwa wí.
7 “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóòmú ọ padà wá.