1 Ní ọdún tí ọba Hùṣáyà kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ḿpìlì.
2 Àwọn Ṣéráfù wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹṣẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò.
3 Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ ogungbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
4 Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹ́ḿpìlì sì kún fún èéfín.
5 “Ègbé ni fún mi!” Ni mo ké, “Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrin àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.
6 Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Ṣéráfù wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní oríi pẹpẹ.