Àìsáyà 66:12-18 BMY

12 Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.

13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínúa ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù.”

14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùnẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15 Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ináàti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.

16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idàni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lóríi gbogbo ènìyàn,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.

17 “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrin àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.

18 “Àti Èmi, nítorí ìgbéṣẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn òrílẹ̀ èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.