13 Lẹ́yìn náà Àìṣáyà sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsìnyí, ìwọ ilé Dáfídì, kò ha tọ́ láti tan ènìyàn ní ṣùúrù, o ó ha tan Ọlọ́run ní ṣùúrù bí?
14 Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.
15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre.
16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
17 Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Éfáímù ti yà kúrò ní Júdà, yóò sì mú ọba Áṣíríà wá.”
18 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Éjíbítì wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Áṣíríà.
19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.