15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre.
16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
17 Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Éfáímù ti yà kúrò ní Júdà, yóò sì mú ọba Áṣíríà wá.”
18 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Éjíbítì wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Áṣíríà.
19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.
20 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹfẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò, ọba Ásíríà, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.
21 Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.