15 Àwọn alàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ni orí,àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì wọ́n lọ́nàÀwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrintàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ́ Ọlọ́run,ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.Ṣíbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúròọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
18 Nítòótọ́ ìkà ń jóni bí iná,ó ń jó àtẹ̀wọ̀n, àtẹ̀gùn run,ó sì ń dáná sun ìgbẹ́tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ń yí lọ sókè ní ọ̀wọ̀n èéfín.
19 Nípaṣẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogunilẹ̀ náà yóò di gbígbẹàwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,ní apá òsì, wọn yóò jẹṣùgbọ́n, kò ní tẹ́wọn lọ́rùn.Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara ọmọ rẹ̀.
21 Mánásè yóò máa jẹ Éfáímù, nígbà tí Éfáímù yóò jẹ Mánásèwọn yóò parapọ̀ dojúkọ Júdà.Ṣíbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúròỌwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.