6 Bi ọlanla rẹ̀ tilẹ goke de ọrun, ti ori rẹ̀ si kan awọsanma.
7 Ṣugbọn yio ṣegbe lailai bi igbẹ́ ara rẹ̀; awọn ti o ti ri i rí, yio wipe, On ha dà?
8 Yio fò lọ bi alá, a kì yio si ri i, ani a o lé e lọ bi iran oru.
9 Oju ti o ti ri i rí pẹlu, kì yio si ri i mọ́, bẹ̃ni ibujoko rẹ̀ kì yio si ri i mọ́.
10 Awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wá ati ri oju-rere lọdọ talaka, ọwọ rẹ̀ yio si kó ẹrù wọn pada.
11 Egungun rẹ̀ kún fun agbara igba ewe rẹ̀, ti yio ba a dubulẹ ninu erupẹ.
12 Bi ìwa buburu tilẹ dùn li ẹnu rẹ̀, bi o tilẹ pa a mọ́ nisalẹ ahọn rẹ̀.