20 Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn.
21 Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade.
22 Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú.
23 Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni:
24 Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada!
25 Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀.
26 O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia.