20 Ninu ìyan yio gbà ọ lọwọ ikú, ati ninu ogun yio gbà ọ lọwọ idà.
21 A o pa ọ mọ kuro lọwọ ìna ahọn, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru iparun nigbati o ba dé.
22 Ẹrin iparun ati ti iyàn ni iwọ o rín, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru ẹranko ilẹ aiye.
23 Nitoripe iwọ o ba okuta ìgbẹ mulẹ̀, awọn ẹranko ìgbẹ yio wà pẹlu rẹ li alafia.
24 Iwọ o si mọ̀ pe alafia ni ibujoko rẹ wà, iwọ o si ma ṣe ibẹ̀wo ibujoko rẹ, iwọ kì yio ṣìna.
25 Iwọ o si mọ̀ pẹlu pe iru-ọmọ rẹ yio si pọ̀, ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ yio ri bi koriko ìgbẹ.
26 Iwọ o wọ isa-okú rẹ lọ li ògbologbo ọjọ bi apo-ọka ti o gbó, ti a si nko ni igbà ikore rẹ̀.