16 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.
17 Ilẹ̀ Júdà yóò da wárìwàrì jó àwọn ará Éjíbítì; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Júdà létíi wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbérò láti ṣe sí wọn.
18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn ún ní ilẹ̀ Éjíbítì yóò sọ èdè àwọn ará Kénánì, wọn yóò sì búra àtìlẹyìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.
19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárin gbùngbùn Éjíbítì, àti ọ̀wọ̀n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀.
20 Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Éjíbítì. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbéjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.
21 Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Éjíbítì àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ oníhóró, wọn yóò jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ.
22 Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn kan bá Éjíbítì jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.