1 Ègbé ni fún òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣeìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Éfáímù,àti sí òdòdó náà tí ń rọ, tí í ṣeògo ẹwàa rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójúàti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tía rẹ̀ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wáìnì!
2 Kíyèsíì, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le tí ó sì lágbára,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wọ́ yìnyín àti bí àtẹ̀gùn apanirun,gẹ́gẹ́ bí àrọ̀ọ̀dá òjò àti òjò tí ómú ẹ̀kún omi wá,òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
3 Òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọnọ̀mùtí Éfáímù,òun ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀.
4 Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkóórèbí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ọ rẹ̀,òun a sì mì ín.
5 Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò jẹ́ adé tí ó lógo,Òdòdó tí ó lẹ́wàfún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
6 Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́-òdodofún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́-ìdájọ́àti oríṣun agbárafún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padàní ẹnubodè.