1 Wòó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodoàwọn olórí yóò máa ṣàkóso ní ìdájọ́.
2 Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò dàbí ìdáàbòbò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,gẹ́gẹ́ bí odò omi nínú aṣálẹ̀àti òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ òrùngbẹ.
3 Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní pàdé mọ́,àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
4 Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
5 A kò ní pe òmùgọ̀ ní bọ̀rọ̀kìnní mọ́tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún mọ̀dàrú.
6 Nítorí òmùgọ̀ ṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀,ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́runó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófoàti fún àwọn tí òrùngbẹ ń gbẹni ó mú omi kúrò.