3 Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní pàdé mọ́,àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
4 Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
5 A kò ní pe òmùgọ̀ ní bọ̀rọ̀kìnní mọ́tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún mọ̀dàrú.
6 Nítorí òmùgọ̀ ṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀,ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́runó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófoàti fún àwọn tí òrùngbẹ ń gbẹni ó mú omi kúrò.
7 Ìlànà àwọn aṣa jẹ ti ìkà,ó pète oríṣìí ìlànà ibiláti pa aláìní run pẹ̀lú irọ́bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ òtòsì sì tọ̀nà.
8 Ṣùgbọ́n bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn a máa pète ohun ńláàti nípa èrò rere ni yóò dúró.
9 Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidiẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!