7 láti la àwọn ojú tí ó fọ́,láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbúàti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀nàwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
8 “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràntàbí ìyìn mi fún ère-òrìṣà.
9 Kíyèsí i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;kí wọn tó hù jádemo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
10 Kọ orin titun sí Olúwaìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,ẹ̀yin tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkun, àtiohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú un wọn.
11 Jẹ́ kí ihà àti àwọn ìlúu rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn ṣókè;jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi kédárì ń gbé máa yọ̀.Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ṣẹ́là kọrin fún ayọ̀;jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.
12 Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwaàti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.
13 Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,gẹ́gẹ́ bí jagunjagun yóò ti gbé ohun ipá rẹ̀ ṣókè;pẹ̀lú ariwo, òun yóò ké igbe ogunòun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀ta rẹ̀.