23 Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí;kígbe ṣókè, Ìwọ ilẹ̀ ayé níṣàlẹ̀.Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,nítorí Olúwa ti ra Jákọ́bù padà,ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Ísírẹ́lì.
24 “Ohun tí Olúwa wí nìyìíOlùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́láti inú ìyá rẹ wá:“Èmi ni Olúwatí ó ti ṣe ohun gbogbotí òun nìkan ti na àwọn ọ̀runtí o sì tẹ́ ayé pẹrẹṣẹ òun tìkálára rẹ̀,
25 “ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́tí ó sì sọ àwọn tí ń woṣẹ́ fún ni di òmùgọ̀,tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọgbọ́n délẹ̀tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
26 ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jádetí ó sì mú àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,“ẹni tí ó wí nípa ti Jérúsálẹ́mù pé,‘a ó máa gbénú un rẹ̀,’àti ní ti àwọn ìlú Júdà, ‘A ó tún un kọ́,’àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀sípò,’
27 ta ni ó sọ fún omi jínjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
28 ta ni ó sọ nípa Ṣáírọ́ọ́ṣì pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn miàti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;òun yóò sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, “Jẹ́ kí a tún un kọ́,”àti nípa tẹ́ḿpìlì, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’