1 “Ṣọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku,wúndíá ọmọbìnrin Bábílónì;jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ láìsí ìtẹ́,ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì.A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.
2 Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun;mú ìbòjú ù rẹ kúrò.Ká yẹ̀rì rẹ sókè, kí o hó ẹṣẹ̀ rẹ sílẹ̀,kí o sì la inú odò lọ.
3 Ìhòòhò rẹ ni a ó fihàn sítaàti ìtìjú rẹ ni a ó sí sílẹ̀.Èmi yóò sì gba ẹ̀ṣan;Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”
4 Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀òun ni Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì.