Àìsáyà 51:7-13 BMY

7 “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun tótọ́,ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyàa yín:Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàntàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.

8 Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ;Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí Ẹ̀gbọ̀n òwú.Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”

9 Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbáraÌwọ apá Olúwa;dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.Ìwọ kọ́ lo ké Rékábù sí wẹ́wẹ́tí o sì fa ewèlè yẹn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?

10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi òkun bíàti àwọn omi inú ọ̀gbun,Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìṣàlẹ̀ òkuntó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?

11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin kíkọ;ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo oríi wọn.Ayọ̀ àti inú-dídùn yóò sì bà lé wọnìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran-ara,àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

13 tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,ẹni tí ó ta àwọn ọ̀runtí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́nítorí ìbínú àwọn aninilára,tí wọ́n sì gbọ́kàn lé ipanirun?Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?