Àìsáyà 53:4-10 BMY

4 Lótìítọ́ ó ti ru àìlera wa lọó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,ṣíbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

5 Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedédé waa pa á lára nítorí àìsòdodo wa;ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lóríi rẹ̀,àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi múwa láradá.

6 Gbogbo wa bí àgùntàn, ti sìnà lọ,ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀gbogbo àìṣedédé wa.

7 A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

8 Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;nítorí àìṣedédé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

9 A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10 Ṣíbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á láraàti láti mú kí ó jìyà,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayérẹ̀ yóò pẹ́ títí,àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.