Àìsáyà 53:7-12 BMY

7 A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

8 Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;nítorí àìṣedédé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

9 A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10 Ṣíbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á láraàti láti mú kí ó jìyà,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayérẹ̀ yóò pẹ́ títí,àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

11 Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;nípa ìmọ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,Òun ni yóò sì ru àìṣedédé wọn

12 Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńláòun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀míi rẹ̀ fún ikú,tí a sì kà á mọ́ àwọn alárèékọjáNítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárèékọjá.