Àìsáyà 63:11-17 BMY

11 Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,àwọn ọjọ́ Mósè àti àwọn ènìyàn rẹ̀níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la òkun já,pẹ̀lú olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?Níbo ni ẹni náà wà tí ó ránẸ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn,

12 ta ni ó rán ògo apá ti agbára rẹ̀láti wà ní apá ọ̀tún Mósè,ta ni ó pín omi níyà níwájú wọn,láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

13 ta ni ó ṣíwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọṣẹ̀;

14 gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa.Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yínláti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.

15 Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí iláti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.Níbo ni ipá àti agbára rẹ wà?Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni atí mú kúrò níwájúu wa.

16 Ṣùgbọ́n ìwọ ni Baba wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù kò mọ̀ wátàbí Ísírẹ́lì mọ ẹni tí à á ṣe;ìwọ, Olúwa ni Baba wa,Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.

17 Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹtí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,àwọn ẹ̀yà tíi ṣe ogún ìní rẹ.