3 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára.
4 Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà.
5 Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan.
6 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin.
7 Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ.
8 Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin.
9 Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ.