Isikiẹli 5 BM

Isikiẹli Gé Irun Rẹ̀

1 OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú idà kan tí ó bá mú, lò ó gẹ́gẹ́ bí abẹ ìfárí, kí o fi fá orí ati irùngbọ̀n rẹ. Mú òṣùnwọ̀n tí a fi ń wọn nǹkan kí o fi pín irun tí o bá fá sí ọ̀nà mẹta.

2 Jó ìdámẹ́ta rẹ̀ ninu iná láàrin ìlú, ní ìgbà tí ọjọ́ tí a fi dóti ìlú náà bá parí. Máa fi idà gé ìdámẹ́ta, kí o sì fọ́n ọn káàkiri lẹ́yìn ìlú, fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri sinu afẹ́fẹ́, n óo sì fa idà yọ tẹ̀lé e.

3 Mú díẹ̀ ninu irun náà kí o dì í sí etí ẹ̀wù rẹ.

4 Mú díẹ̀ ninu èyí tí o dì sí etí ẹ̀wù, jù ú sinu iná kí ó jóná; iná yóo sì ti ibẹ̀ ṣẹ́ sí gbogbo ilé Israẹli.”

5 OLUWA Ọlọrun ní: “Jerusalẹmu nìyí. Mo ti fi í sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì ti fi àwọn agbègbè yí i ká.

6 Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi.

7 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká.

8 Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè.

9 Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae.

10 Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé.

11 “Bí mo ti wà láàyè, n óo pa yín run. N kò ní fojú fo ohunkohun, n kò sì ní ṣàánú yín rárá; nítorí ẹ ti fi àwọn nǹkan ẹ̀sìn ìríra ati àṣà burúkú yín sọ ilé mímọ́ mi di aláìmọ́.

12 Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n.

13 “Bẹ́ẹ̀ ni inú mi yóo ṣe máa ru si yín, tí n óo sì bínú si yín títí n óo fi tẹ́ ara mi lọ́rùn. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀ pẹlu owú nígbà tí mo bá bínú si yín tẹ́rùn.

14 N óo sọ yín di ahoro ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yi yín ká ati lójú gbogbo àwọn tí wọn ń rékọjá lọ.

15 “Ẹ óo di ẹni ẹ̀sín ati ẹni ẹ̀gàn, ẹni àríkọ́gbọ́n ati ẹni àríbẹ̀rù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká; nígbà tí mo bá fi ibinu ati ìrúnú dájọ́ fun yín, tí mo sì jẹ yín níyà pẹlu ibinu.

16 Nígbà tí mo bá ta ọfà burúkú mi si yín: ọfà ìyàn ati ọfà ìparun, tí n óo ta lù yín láti pa yín run, ìyàn óo mú lọpọlọpọ nígbà tí mo bá mú kí oúnjẹ yín tán pátá.

17 N óo rán ìyàn ati àwọn ẹranko burúkú si yín, wọn óo sì pa yín lọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, n óo sì jẹ́ kí ogun pa yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”