Isikiẹli 19 BM

Orin Arò

1 OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli,

2 kí n sọ pé:Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun!Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun,ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

3 Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà;ó di ọ̀dọ́ kinniun.Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ,ó sì ń pa eniyan jẹ.

4 Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀,wọ́n tàn án sinu kòtò wọn.Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú,wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti.

5 Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun,ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo,ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀,ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun.

6 Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun;nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára,ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ,ó sì ń pa eniyan jẹ.

7 Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀;ó sọ ìlú wọn di ahoro.Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀,nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀.

8 Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un.

9 Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.

10 Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbàtí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.

11 Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbárani a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.

12 Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,a sì jù ú sílẹ̀.Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.

13 Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀,ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi.

14 Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀,ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀.Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́,tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba.Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.