1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí àwọn ará Amoni kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn.
3 Wí fún wọn báyìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí; nítorí pé ẹ̀ ń yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ẹ̀ ń yọ ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ẹ sì ń yọ ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n kó o lọ sí ìgbèkùn;
4 nítorí náà, n óo fà yín lé àwọn ará ilẹ̀ ìlà oòrùn lọ́wọ́, ẹ óo sì di tiwọn. Wọn óo pa àgọ́ sí ààrin yín; wọn óo tẹ̀dó sí ààrin yín; wọn óo máa jẹ èso oko yín, wọn óo sì máa mu wàrà yín.
5 N óo sọ ìlú Raba di pápá àwọn ràkúnmí, àwọn ìlú Amoni yóo sì di pápá ẹran. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!’
6 Nitori báyìí ni OLUWA Ọlọrun wí, “Ẹ̀yin ń pàtẹ́wọ́, ẹ̀ ń fò sókè, ẹ sì ń yọ àwọn ọmọ Israẹli.
7 Nítorí náà, ẹ wò ó! Mo ti nawọ́ ìyà si yín, n óo sì fi yín ṣe ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. N óo pa yín run láàrin àwọn eniyan ilẹ̀ ayé, n óo sì pa yín rẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
8 OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Moabu ń wí pé ilẹ̀ Juda dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
9 nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká.
10 N óo fún àwọn ará ìlà oòrùn ní òun ati ilẹ̀ Amoni, wọn óo di ìkógun, kí á má baà ranti rẹ̀ mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
11 N óo ṣe ìdájọ́ àwọn ará Moabu; wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!”
12 OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí àwọn ará Edomu gbẹ̀san lára àwọn ará Juda, wọ́n sì ṣẹ̀ nítorí ẹ̀san tí wọ́n gbà.
13 N óo nawọ́ ìyà sí Edomu, n óo pa ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀ run. N óo sọ ọ́ di ahoro láti Temani títí dé Dedani. Ogun ni yóo pa wọ́n.
14 Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
15 OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Filistia gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn, wọn sì fi ìkórìíra àtayébáyé pa wọ́n run,
16 nítorí náà, n óo nawọ́ ìyà sí wọn, n óo pa àwọn ọmọ Kereti run, n óo pa àwọn tí ó kù sí etí òkun rẹ́.
17 N óo gbẹ̀san lára wọn lọpọlọpọ; n óo fi ìrúnú fi ìyà ńlá jẹ wọ́n. Wọn óo wá mọ̀ nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn pé èmi ni OLUWA.”