Isikiẹli 20 BM

Ìfẹ́ OLUWA ati Àìbìkítà Eniyan

1 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi.

2 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

3 “Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’

4 “Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe.

5 Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

6 Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé.

7 Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

8 Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti.

9 Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀.

10 “Nítorí náà, mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wá sinu aṣálẹ̀.

11 Mo fún wọn ní òfin mi, mo sì fi ìlànà mi hàn wọ́n, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè.

12 Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́.

13 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀.

14 Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.

15 Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé.

16 Nítorí pé wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọn kò tẹ̀lé òfin mi, wọ́n sì ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, nítorí pé ọkàn wọn kò kúrò lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn.

17 “Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀.

18 Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn.

19 Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́.

20 Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín.

21 “Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀.

22 Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.

23 Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

24 nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ.

25 “Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là.

26 Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

27 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

28 Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀.

29 Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní.

30 Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn?

31 Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi.

32 Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta.

Ọlọrun a máa Fi Ìyà Jẹ Ẹlẹ́ṣẹ̀ a sì máa Dáríjì

33 “Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín.

34 N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu.

35 N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju.

36 Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

37 “N óo mú kí ẹ gba abẹ́ ọ̀pá mi kọjá, n óo sì mu yín wá sí abẹ́ ìdè majẹmu.

38 N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

39 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA Ọlọrun ní, “Kí olukuluku yín lọ máa bọ oriṣa rẹ̀ láti ìsinsìnyìí lọ, bí ẹ kò bá fẹ́ gbọ́ tèmi, ṣugbọn ẹ kò ní fi ẹbọ ati oriṣa yín ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.

40 Lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni gbogbo ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli yóo ti máa sìn mí. Gbogbo yín pátá ní ilẹ̀ náà, ni ẹ óo máa sìn mí níbẹ̀. N óo yọ́nú si yín. N óo sì bèèrè ọrẹ àdájọ lọ́wọ́ yín ati ọrẹ àtinúwá tí ó dára jùlọ pẹlu ẹbọ mímọ́ yín.

41 N óo yọ́nú si yín bí ìgbà tí mo bá gbọ́ òórùn ẹbọ dídùn, nígbà tí mo bá ń ko yín jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mò ń ko yín jọ kúrò láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè tí ẹ fọ́nká sí. Ẹwà mímọ́ mi yóo sì hàn lára yín lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù.

42 Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ko yín dé ilẹ̀ Israẹli, ilẹ̀ tí mo búra láti fún àwọn baba ńlá yín.

43 Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, ẹ óo ranti ìṣe yín, ati gbogbo ìwà èérí tí ẹ hù tí ẹ fi ba ara yín jẹ́. Ojú ara yín yóo sì tì yín nígbà tí ẹ bá ranti gbogbo nǹkan burúkú tí ẹ ti ṣe.

44 Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ba yín wí nítorí orúkọ mi, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà burúkú yín tabi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà burúkú yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Iná Yóo Jó Ní gúsù

45 OLUWA sọ fún mi pé,

46 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí ìhà gúsù, fi iwaasu bá ìhà ibẹ̀ wí, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ilẹ̀ igbó Nẹgẹbu.

47 Sọ fún igbó ibẹ̀ pé èmi OLUWA Ọlọrun ní n óo sọ iná sí i, yóo sì jó gbogbo àwọn igi inú rẹ̀, ati tútù ati gbígbẹ, iná náà kò ní kú. Yóo jó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní gúsù títí dé àríwá.

48 Gbogbo eniyan ni yóo rí i pé èmi OLUWA ni mo dá iná náà, kò sì ní ṣe é pa.”

49 Mo bá dáhùn pé, “Áà! OLUWA Ọlọrun, wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ǹjẹ́ òun fúnrarẹ̀ kọ́ ni ó ń ro òwe yìí, tí ó sì ń pa á mọ́ wa?’ ”