Isikiẹli 18 BM

Iṣẹ́ Ẹnìkọ̀ọ̀kan

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó bi mí pé:

2 “Kí ni ẹ rí tí ẹ fi ń pa irú òwe yìí nípa ilẹ̀ Israẹli, tí ẹ̀ ń sọ pé,‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà tí ó kan,ni eyín fi kan àwọn ọmọ?’

3 “Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní pa òwe yìí mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.

4 Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.

5 “Bí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu;

6 bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́;

7 tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò,

8 tí kò gba owó èlé lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ láàrin ẹni meji,

9 tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

10 “Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí ń fi ipá jalè, tí ń pa eniyan, tí kò ṣe ọ̀kankan ninu gbogbo ohun tí a kà sílẹ̀ pé baba ń ṣe,

11 ṣugbọn tí ó ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí ó ń bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀;

12 tí ń ni talaka ati aláìní lára, tí ń fi ipá jalè, tí kì í dá ohun tí onígbèsè rẹ̀ bá fi ṣe ìdúró pada fún un, tí ń bọ oriṣa, tí ń ṣe ohun ìríra,

13 tí ń gba owó èlé; ǹjẹ́ irú eniyan bẹ́ẹ̀ lè yè? Kò lè yè rárá. Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, yóo kú ni dájúdájú; lórí ara rẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.

14 “Ṣugbọn bí eniyan burúkú yìí bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ń dá, tí ẹ̀rù bà á, tí kò sì ṣe bíi baba rẹ̀,

15 tí kì í jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí kò bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli, tí kò bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀,

16 tí kò ṣẹ ẹnikẹ́ni; tí Kì í gba ohun ìdúró lọ́wọ́ onígbèsè, tí kì í fi ipá jalè, ṣugbọn tí ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò,

17 tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí kì í gba owó èlé, tí ń pa òfin mi mọ́, tí sì ń rìn ninu ìlànà mi, kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, dájúdájú yóo yè.

18 Baba rẹ̀ yóo kú ní tirẹ̀, nítorí pé ó ń fi ipá gbowó, ó ń ja arakunrin rẹ̀ lólè, ó sì ń ṣe ohun tí kò dára sí àwọn eniyan rẹ̀; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni yóo ṣe kú.

19 “Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí ló dé tí ọmọ kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ bá ti ṣe ohun tí ó bá òfin mu, tí ó sì ti mú gbogbo ìlànà mi ṣẹ; dájúdájú yóo yè ni.

20 Ẹni tí ó bá ṣẹ̀ ni yóo kú: ọmọ kò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀; baba kò sì ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo yóo jèrè òdodo rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan burúkú yóo jèrè ìwà burúkú rẹ̀.

21 “Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú.

22 A kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóo yè nítorí òdodo rẹ̀.”

23 OLUWA ní: “A máa ṣe pé mo ní inú dídùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni? Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò lọ́nà burúkú rẹ̀, kí ó sì yè.

24 “Ṣugbọn bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, tí ó ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn eniyan burúkú ń ṣe; ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ leè yè? Rárá! A kò ní ranti gbogbo òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe mọ́, yóo kú nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ ati ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

25 “Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: ọ̀nà tèmi ni kò tọ́ ni, àbí ọ̀nà tiyín?

26 Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

27 Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ìwà ibi rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

28 Nítorí pé ó ronú, ó sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ń dá, dájúdájú yóo yè, kò ní kú.

29 Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ọ̀nà mi ni kò tọ́, àbí tiyín?

30 “Nítorí náà, n óo da yín lẹ́jọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ìwà olukuluku ni n óo fi dá a lẹ́jọ́. Ẹ ronupiwada, kí ẹ sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà pa yín run. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31 Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli?

32 N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”