Isikiẹli 30 BM

OLUWA Yóo Jẹ Ijipti Níyà

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé, OLUWA Ọlọrun ní,

3 ‘Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí ọjọ́ burúkú tí ń bọ̀,nítorí ọjọ́ náà súnmọ́lé,ọjọ́ OLUWA ti dé tán,yóo jẹ́ ọjọ́ ìṣúduduati ìparun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Ogun yóo jà ní Ijipti,ìrora yóo sì bá Etiopia.Nígbà tí ọpọlọpọ òkú bá sùn ní Ijipti,tí a kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ,tí a sì wó ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀.

5 “ ‘Àwọn ará Etiopia, ati Puti, ati Ludi, ati gbogbo ilẹ̀ Arabia ati Libia, ati gbogbo àwọn eniyan wa tí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀, ni ogun yóo pa.’ ”

6 OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú,ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀;láti Migidoli títí dé Siene,wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

7 “Ijipti óo di ahoro patapata àwọn ìlú rẹ̀ yóo wà lára àwọn ìlú tí yóo tú patapata.

8 Wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá dáná sun Ijipti, tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá ṣubú.

9 “Nígbà tó bá tó àkókò, n óo rán àwọn ikọ̀ ninu ọkọ̀ ojú omi, wọn ó lọ dẹ́rù ba àwọn ará Etiopia tí wọn ń gbé láìfura. Wahala yóo dé bá àwọn ará Etiopia ní ọjọ́ ìparun Ijipti. Wò ó, ìparun náà ti dé tán.”

10 OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ti ọwọ́ Nebukadinesari, ọba Babiloni, fi òpin sí ọrọ̀ Ijipti.

11 Òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè oníjàgídíjàgan jùlọ ni, yóo wá pa ilẹ̀ Ijipti run, wọn yóo yọ idà ti Ijipti, ọpọlọpọ yóo sì kú ní ilẹ̀ náà.

12 N óo mú kí odò Naili gbẹ, n óo ta ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan burúkú; n óo sì jẹ́ kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di ahoro. Èmi OLUWA ní mo sọ bẹ́ẹ̀.”

13 OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fọ́ àwọn ère tí ó wà ní Memfisi, n óo sì pa wọ́n run. Kò ní sí ọba ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, n óo jẹ́ kí ìbẹ̀rù dé bá ilẹ̀ Ijipti.

14 N óo sọ Patirosi di ahoro, n óo sì dáná sun Soani, n óo sì ṣe ìdájọ́ fún ìlú Tebesi.

15 N óo bínú sí Pelusiumu, ibi ààbò Ijipti, n óo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ń gbé Tebesi.

16 N óo dáná sun Ijipti, Pelusiumu yóo sì wà ninu ìrora ńlá.

17 N óo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Oni ati ti Pibeseti; a óo sì kó àwọn obinrin wọn lọ sí ìgbèkùn.

18 Ojú ọjọ́ yóo ṣókùnkùn ní Tehafinehesi nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá ìjọba Ijipti, agbára tí ó ń gbéraga sí yóo sì dópin. Ìkùukùu óo bò ó mọ́lẹ̀; wọn óo sì kó àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.

19 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ṣe ìdájọ́ Ijipti, wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

A Ṣẹ́ Agbára Ọba Ijipti

20 Ní ọjọ́ keje, oṣù kinni ọdún kọkanla, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

21 “Ìwọ ọmọ eniyan, mo ti ṣẹ́ Farao, ọba Ijipti, lápá, a kò sì tíì dí i, kí ọgbẹ́ rẹ̀ fi san, kí ó sì fi lágbára láti gbá idà mú.

22 Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

23 N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká orílẹ̀-èdè ayé, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé.

24 N óo fún ọba Babiloni lágbára, n óo sì fi idà mi lé e lọ́wọ́; ṣugbọn n óo ṣẹ́ Farao lápá; yóo máa kérora níwájú rẹ̀ bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́ tí ó ń kú lọ.

25 N óo fún ọba Babiloni lágbára, ṣugbọn ọwọ́ Farao yóo rọ. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Nígbà tí mo bá fi idà mi lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo fa idà náà yọ yóo gbógun ti ilẹ̀ Ijipti.

26 N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”