1 Ní ọjọ́ kinni oṣù kejila, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀.
2 Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbé ohùn sókè kí o kọ orin arò nípa Farao, ọba Ijipti. Wí fún un pé ó ka ara rẹ̀ kún kinniun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ó dàbí diragoni ninu omi. Ó ń jáde tagbára tagbára láti inú odò, ó ń fẹsẹ̀ da omi rú, ó sì ń dọ̀tí àwọn odò.
3 Sọ pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní n óo da àwọ̀n mi bò ó níṣojú ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan; wọn óo sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ sókè.
4 N óo wọ́ ọ jù sórí ilẹ̀; inú pápá ni n óo sọ ọ́ sí, n óo jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run pa ìtẹ́ wọn lé e lórí. N óo sì jẹ́ kí àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé jẹ ẹran ara rẹ.
5 N óo sọ ẹran ara rẹ̀ káàkiri sí orí àwọn òkè. N óo sì fi òkú rẹ̀ kún àwọn àfonífojì.
6 N óo tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà sórí ilẹ̀ ati sórí àwọn òkè, gbogbo ipadò yóo sì kún fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
7 Nígbà tí mo bá pa á rẹ́, n óo bo ojú ọ̀run; n óo jẹ́ kí ìràwọ̀ ṣóòkùn n óo fi ìkùukùu bo oòrùn lójú, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.
8 Gbogbo àwọn ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tàn lójú ọ̀run ni n óo jẹ́ kí ó di òkùnkùn lórí rẹ̀, n óo jẹ́ kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9 “N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé.
10 N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.”
11 OLUWA Ọlọrun sọ fún ọba Ijipti pé, “Ọba Babiloni yóo fi idà pa yín.
12 N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun.
13 N óo pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Ijipti tí ó wà ní etí odò run. Àwọn eniyan kò sì ní fi ẹsẹ̀ da omi rú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko kò ní fi pátákò da odò rú mọ́.
14 N óo wá jẹ́ kí odò wọn ó tòrò, kí wọn máa ṣàn bí òróró. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
15 Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro, tí mo bá pa gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ run; tí mo bá pa gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ run, wọn yóo mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.
16 Àwọn eniyan yóo máa kọ ọ̀rọ̀ yìí ní orin arò; àwọn ọmọbinrin ní àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa kọ ọ́. Wọn óo máa kọ ọ́ nípa Ijipti ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Èmi, OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
17 Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn,
18 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan Ijipti, rán àwọn ati àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá yòókù lọ sinu isà òkú, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ilẹ̀ bora.
19 Sọ fún wọn pé,‘Ta ni ó lẹ́wà jùlọ?Sùn kalẹ̀, kí á sì tẹ́ ọ sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.’
20 “Wọn yóo ṣubú láàrin àwọn tí wọ́n kú ikú ogun; ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ yóo ṣubú pẹlu rẹ̀.
21 Àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ akọni ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn yóo máa sọ nípa wọn ninu isà òkú pé, ‘Àwọn aláìkọlà tí a fi idà pa ti ṣubú, wọ́n ti wọlẹ̀, wọ́n sùn, wọn kò lè mira.’
22 “Asiria náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ibojì àwọn tí wọ́n ti kú yí i ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.
23 Ibojì rẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun isà òkú. Ibojì àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì tò yí tirẹ̀ ká. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láyé, gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.
24 “Elamu náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. Wọ́n sì lọ sinu isà òkú ní àìkọlà abẹ́. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè, wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, wọn lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú.
25 Wọ́n tẹ́ ibùsùn fún Elamu láàrin àwọn tí wọ́n kú sójú ogun pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Ibojì wọn yí tirẹ̀ ká, gbogbo wọn ni a fi idà pa láìkọlà abẹ́. Wọ́n ń dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ, wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. A kó gbogbo wọn pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kú sójú ogun.
26 “Meṣeki ati Tubali wà níbẹ̀ pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan wọn. Ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n kú lójú ogun ní aláìkọlà. Nítorí wọ́n ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.
27 Wọn kò sin wọ́n bí àwọn alágbára tí wọ́n wà ní àtijọ́ tí wọ́n sin sí ibojì pẹlu ohun ìjà ogun wọn lára wọn: àwọn tí a gbé orí wọn lé idà wọn, wọ́n sì fi asà wọn bo egungun wọn mọ́lẹ̀; nítorí àwọn alágbára wọnyi dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.
28 “Nítorí náà, a óo wó ọ mọ́lẹ̀, o óo sì sùn láàrin àwọn aláìkọlà pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.
29 “Edomu náà wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Bí wọ́n ti lágbára tó, wọ́n sùn pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Wọ́n sùn pẹlu àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.
30 “Gbogbo àwọn olórí láti apá àríwá wà níbẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Sidoni, tí wọ́n fi ìtìjú wọlé lọ sí ipò òkú pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo agbára wọn láti dẹ́rù bani, wọ́n sùn láìkọlà, pẹlu ìtìjú, pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Pẹlu àwọn tí wọ́n lọ sinu isà òkú.
31 “Nígbà tí Farao bá rí wọn, Tòun ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, yóo dá ara rẹ̀ lọ́kàn le, nítorí gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
32 “Mo mú kí Farao dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí ó wà láyé. Nítorí náà, a óo sin òun ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ sí ààrin àwọn aláìkọlà, láàrin àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun wí.