Isikiẹli 46 BM

Àwọn Ọba ati Àwọn Àjọ̀dún

1 OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹnu ọ̀nà àgbàlá inú tí ó kọjú sí ìlà oòrùn gbọdọ̀ wà ní títì fún ọjọ́ mẹfa tí a fi ń ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ẹ máa ṣí i ní ọjọ́ ìsinmi ati ọjọ́ oṣù tuntun.

2 Yàrá àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni ọba yóo gbà wọlé, yóo sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ẹnu ọ̀nà. Àwọn alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ti alaafia rẹ̀. Ọba yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbájáde, yóo sì jáde; ṣugbọn wọn kò ní ti ìlẹ̀kùn náà títí di ìrọ̀lẹ́.

3 Àwọn eniyan yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níwájú OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi ati ní ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.

4 Ọ̀dọ́ aguntan mẹfa tí kò lábàwọ́n ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n ni ọba yóo fi rú ẹbọ ọrẹ sísun sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi.

5 Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.

6 Ní ọjọ́ kinni oṣù, yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan mẹfa ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n rúbọ.

7 Fún ẹbọ ohun jíjẹ, yóo tọ́jú ìwọ̀n eefa ọkà kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ati eefa ọkà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n ọkà tí ó bá ti lágbára fún àwọn àgbò, yóo fi hini òróró kọ̀ọ̀kan ti eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.

8 Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà ni ọba yóo gbà wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.

9 “Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará ìlú bá wá siwaju OLUWA ní àkókò àjọ̀dún, ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà apá àríwá wọlé, ẹnu ọ̀nà gúsù ni ó gbọdọ̀ gbà jáde, ẹni tí ó bá sì gba ẹnu ọ̀nà gúsù wọlé, ẹnu ọ̀nà àríwá ni ó gbọdọ̀ gbà jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tó gbà wọlé jáde. Tààrà ni kí olukuluku máa lọ títí yóo fi jáde.

10 Ọba yóo bá wọn wọlé nígbà tí wọ́n bá wọlé, nígbà tí wọ́n bá sì jáde, yóo bá wọn jáde.

11 Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.

12 “Nígbà tí ọba bá pèsè ẹbọ ọrẹ àtinúwá, kì báà ṣe ẹbọ sísun, tabi ẹbọ alaafia, ni ọrẹ àtinúwá fún OLUWA tí ó pèsè, wọn yóo ṣí ẹnubodè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn fún un, yóo sì rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia rẹ̀ bíi ti ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà yóo jáde, wọn óo sì ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà.”

Ẹbọ Ojoojumọ

13 OLUWA ní, “Yóo máa pèsè ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n fún ẹbọ sísun sí OLUWA lojoojumọ. Láràárọ̀ ni yóo máa pèsè rẹ̀.

14 Ẹbọ ohun jíjẹ tí yóo máa pèsè pẹlu rẹ̀ láràárọ̀ ni: ìdámẹ́fà eefa ìyẹ̀fun ati ìdámẹ́ta hini òróró tí wọn yóo fi máa po ìyẹ̀fun náà fún ẹbọ ohun jíjẹ fún OLUWA. Èyí ni yóo jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

15 Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo ṣe máa pèsè aguntan ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró láràárọ̀, fún ẹbọ ọrẹ sísun ìgbà gbogbo.”

Ọba ati Ilẹ̀ Náà

16 OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ọba bá fún ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di ti àwọn ọmọ rẹ̀, ó di ohun ìní wọn tí wọ́n jogún.

17 Ṣugbọn bí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di tirẹ̀ títí di ọjọ́ tí yóo gba òmìnira; láti ọjọ́ náà ni ilẹ̀ náà yóo ti pada di ti ọba. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ni wọ́n lè jogún ilẹ̀ rẹ̀ títí lae.

18 Ọba kò gbọdọ̀ gbà ninu ilẹ̀ àwọn ará ìlú láti ni wọ́n lára; ninu ilẹ̀ tirẹ̀ ni kí ó ti pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má baà gba ilẹ̀ ọ̀kankan ninu àwọn eniyan mi kúrò lọ́wọ́ wọn.”

Àwọn Ilé Ìdáná Tẹmpili

19 Ọkunrin náà bá mú mi gba ọ̀nà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn, ó bá mú mi lọ sí ibi àwọn yàrá tí ó wà ní apá àríwá ibi mímọ́ náà, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa, mo sì rí ibìkan níbẹ̀ tí ó wà ní ìpẹ̀kun ní apá ìwọ̀ oòrùn.

20 OLUWA wá sọ fún mi pé, “Ní ibí yìí ni àwọn alufaa yóo ti máa se ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ibẹ̀ ni wọn yóo sì ti máa ṣe burẹdi fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọn má baà kó wọn jáde wá sí gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, kí wọn má baà fi ohun mímọ́ kó bá àwọn eniyan.”

21 Ọkunrin náà bá mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, ó mú mi yíká gbogbo igun mẹrẹẹrin gbọ̀ngàn náà, gbọ̀ngàn kéékèèké kọ̀ọ̀kan sì wà ní igun kọ̀ọ̀kan.

22 Ní igun mẹrẹẹrin ni àwọn gbọ̀ngàn kéékèèké yìí wà. Ó gùn ní ogoji igbọnwọ (mita 20), ó sì fẹ̀ ní ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 15) àwọn mẹrẹẹrin sì rí bákan náà.

23 Wọ́n fi òkúta kọ́ igun mẹrẹẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípo. Wọ́n sì kọ́ ibi ìdáná wọn mọ́ ara ògiri.

24 Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Àwọn ilé ìdáná níbi tí àwọn alufaa tí óo wà níbi pẹpẹ yóo ti máa se ẹran ẹbọ àwọn eniyan mi nìyí.”