1 OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú bulọọku kan kí o gbé e ka iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sórí rẹ̀.
2 Kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń dóti ìlú tì í. Bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ọ̀nà dé ibẹ̀. Fi àgọ́ àwọn jagunjagun sí i, kí o wá gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká.
3 Wá irin pẹlẹbẹ kan tí ó fẹ̀, kí o gbé e sí ààrin ìwọ ati ìlú náà, kí ó dàbí ògiri onírin. Dojú kọ ọ́ bí ìlú tí a gbógun tì; kí o ṣebí ẹni pé ò ń gbógun tì í. Èyí yóo jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.
4 “Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀.
5 Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.
6 Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.
7 “Lẹ́yìn náà, kọjú sí Jerusalẹmu, ìlú tí a gbógun tì, ká aṣọ kúrò ní apá rẹ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i.
8 Wò ó! N óo dè ọ́ lókùn mọ́lẹ̀, tí o kò fi ní lè yí ẹ̀gbẹ́ pada títí tí o óo fi parí iye ọjọ́ tí o níláti fi gbé ogun tì í.
9 “Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.
10 Wíwọ̀n ni o óo máa wọn oúnjẹ tí o óo máa jẹ, ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ rẹ yóo jẹ́ ogún ṣekeli, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa jẹ ẹ́.
11 Wíwọ̀n ni o óo máa wọn omi tí o óo máa mu pẹlu; ìdá mẹfa òṣùnwọ̀n hini ni omi tí o óo máa mu ní ọjọ́ kan, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa mu ún.
12 O óo jẹ ẹ́ bí àkàrà ọkà baali dídùn; ìgbẹ́ eniyan ni o óo máa fi dá iná tí o óo máa fi dín in lójú wọn.”
13 OLUWA ní: “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn ní àìmọ́, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí òun óo lé wọn sí.”
14 Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, n kò sọ ara mi di aláìmọ́ rí láti ìgbà èwe mi títí di ìsinsìnyìí, n kò jẹ òkú ẹran rí, tabi ẹran tí ẹranko pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kankan kò kan ẹnu mi rí.”
15 OLUWA bá wí fún mi pé, “Kò burú, n óo jẹ́ kí o fi ìgbẹ́ mààlúù dáná láti fi dín àkàrà rẹ, dípò ìgbẹ́ eniyan.”
16 Ó tún fi kun fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, n óo mú kí oúnjẹ wọ́n ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rù ni wọn óo máa fi wá oúnjẹ tí wọn óo máa jẹ, wíwọ̀n ni wọn óo sì máa wọn omi mu pẹlu ìpayà.
17 N óo ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè ṣe aláìní oúnjẹ ati omi, kí wọ́n lè máa wo ara wọn pẹlu ìpayà, kí wọ́n sì parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”