1 Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi.
2 OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀,
3 ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?
4 “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.
5 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada.
6 “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ
7 “Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn.
8 N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
9 “Bí wolii kan bá jẹ́ kí á ṣi òun lọ́nà, tí ó sì sọ̀rọ̀, a jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo jẹ́ kí wolii náà ṣìnà, N óo na ọwọ́ ìyà sí i, n óo sì pa á run kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi.
10 Àwọn mejeeji yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Irú ìyà kan náà ni n óo fi jẹ wolii alára ati ẹni tí ó lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
11 N óo ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli má baà ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, tabi kí ẹ máa fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Ṣugbọn kí ẹ lè jẹ́ eniyan mi, kí n sì jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
12 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
13 “Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀,
14 bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
15 “Bí mo bá jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú já wọ orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n pa wọ́n lọ́mọ jẹ, tí wọ́n sọ ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò lè gba ibẹ̀ kọjá mọ́, nítorí àwọn ẹranko tí wọ́n wà níbẹ̀,
16 bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro.
17 Bí mo bá mú kí ogun jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀,
18 bí àwọn ọkunrin mẹta náà bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA ti wà láàyè, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà.
19 “Tabi bí mo bá rán àjàkálẹ̀ àrùn sí orílẹ̀-èdè náà, tí mo sì fi ibinu bá a jà, débi pé eniyan kú níbẹ̀, tí mo pa ati eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀,
20 bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.”
21 Nítorí OLUWA Ọlọrun ní, “Báwo ni yóo ti wá burú tó nisinsinyii tí mo rán ìjẹníyà burúkú mẹrin wọnyi sí Jerusalẹmu: ogun, ìyàn, ẹranko burúkú ati àjàkálẹ̀ àrùn láti pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀.
22 Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu.
23 Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”