Isikiẹli 24 BM

Ìkòkò Ìdáná tí Ó Dípẹtà

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹwaa, oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an tí a ti wà ní ìgbèkùn, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sàmì sí ọjọ́ òní, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀. Lónìí gan-an ni ọba Babilonia gbógun ti Jerusalẹmu.

3 Pa òwe yìí fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kí o sì wí fún wọn pé, ní orúkọ èmi OLUWA Ọlọrun: Gbé ìkòkò kaná;bu omi sí i.

4 Kó ègé ẹran sí i,gbogbo ibi tí ó dára jùlọ lára ẹran,ẹran itan ati ti èjìká,kó egungun tí ó dára náà sí i kí ó kún.

5 Ẹran tí ó dára jùlọ ninu agbo ni kí o mú,kó igi jọ sí abẹ́ ìkòkò náà,kí o bọ ẹran náà,bọ̀ ọ́ teegunteegun.”

6 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú apànìyàn, ìkòkò tí inú rẹ̀ dípẹtà, tí ìdọ̀tí rẹ̀ kò ṣí kúrò ninu rẹ̀! Yọ ẹran inú rẹ̀ kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, sá máa mú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti bà.

7 Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ eniyan tí ó pa wà ninu rẹ̀, orí àpáta ni ó da ẹ̀jẹ̀ wọn sí, kò dà á sórí ilẹ̀, tí yóo fi rí erùpẹ̀ bò ó.

8 Mo ti da ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ sórí àpáta, kí ó má baà ṣe é bò mọ́lẹ̀. Kí inú lè bí mi, kí n lè gbẹ̀san.”

9 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí, èmi fúnra mi ni n óo kó iná ńlá jọ.

10 Ẹ kó ọpọlọpọ igi jọ; ẹ ṣáná sí i. Ẹ se ẹran náà dáradára, ẹ da omi rẹ̀ nù, kí ẹ jẹ́ kí egungun rẹ̀ jóná.

11 Lẹ́yìn náà, ẹ gbé òfìfo ìkòkò náà léná, kí ó gbóná, kí idẹ inú rẹ̀ lè yọ́; kí ìdọ̀tí tí ó wà ninu rẹ̀ lè jóná, kí ìpẹtà rẹ̀ sì lè jóná pẹlu.

12 Lásán ni mò ń ṣe wahala, gbogbo ìpẹtà náà kò ní jóná.

13 Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn.

14 Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Iyawo Wolii Náà Kú

15 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16 “Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ.

17 O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.”

18 Mo bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ láàárọ̀, nígbà tí ó di àṣáálẹ́, iyawo mi kú. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí n ṣe.

19 Àwọn eniyan bá bi mí pé, “Ṣé kò yẹ kí o sọ ohun tí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa, tí o fi ń ṣe báyìí.”

20 Mo bá sọ fún wọn pé, “OLUWA ni ó bá mi sọ̀rọ̀,

21 tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀.

22 Bí mo ti ṣe yìí gan-an ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe, ẹ kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu yín tabi kí ẹ máa jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.

23 Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn.

24 Ó ní èmi Isikiẹli óo jẹ́ àmì fun yín, gbogbo bí mo bá ti ṣe ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹlẹ̀. Ẹ óo sì mọ̀ pé òun ni OLUWA Ọlọrun.”

25 OLUWA ní, “Ìwọ ní tìrẹ, ọmọ eniyan, ní ọjọ́ tí mo bá gba ibi ààbò wọn lọ́wọ́ wọn, àní ayọ̀ ati ògo wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ máa rí, tí ọkàn wọn sì fẹ́, pẹlu àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin,

26 ní ọjọ́ náà, ẹnìkan tí yóo sá àsálà ni yóo wá fún ọ ní ìròyìn.

27 Ní ọjọ́ náà, ẹnu rẹ óo yà, o óo sì le sọ̀rọ̀; o kò ní ya odi mọ́. Ìwọ ni o óo jẹ́ àmì fún wọn; wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”