Isikiẹli 44 BM

Lílo Ẹnu Ọ̀nà Ìlà Oòrùn

1 Lẹ́yìn náà ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ìta ibi mímọ́ tí ó kọjú sí ìlà oòrùn, ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà wà ní títì.

2 OLUWA wí fún mi pé, “Ìlẹ̀kùn yìí yóo máa wà ní títì ni, wọn kò gbọdọ̀ ṣí i; ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé, nítorí èmi OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ti gba ibẹ̀ wọlé. Nítorí náà, títì ni yóo máa wà.

3 Ọba nìkan ni ó lè jókòó níbẹ̀ láti jẹun níwájú OLUWA. Yóo gba ẹnu ọ̀nà ìloro wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.”

Òfin tí Ó De Wíwọ Tẹmpili

4 Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wá siwaju tẹmpili; mo sì rí i tí ìtànṣán ògo OLUWA kún inú tẹmpili, mo bá dojúbolẹ̀.

5 OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé.

6 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olóríkunkun, pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ dáwọ́ àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe dúró.

7 Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́.

8 Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀.

9 “ ‘Nítorí náà, ẹni tí kò bá kọlà ọkàn ati ti ara ninu àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

A Yọ Àwọn Ọmọ Lefi Kúrò ninu Iṣẹ́ Alufaa

10 OLUWA ní, “Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada lẹ́yìn mi, tí wọ́n ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn nígbà tí Israẹli ṣáko lọ, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11 Wọ́n lè jẹ́ iranṣẹ ninu ibi mímọ́ mi, wọ́n lè máa ṣe alákòóso àwọn ẹnu ọ̀nà tẹmpili, wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, wọ́n lè máa pa ẹran ẹbọ sísun ati ẹran ẹbọ àwọn eniyan, wọ́n lè máa ṣe iranṣẹ fún àwọn eniyan.

12 Nítorí pé wọ́n ti jẹ́ iranṣẹ fún wọn níwájú àwọn oriṣa, wọ́n sì di ohun ìkọsẹ̀ tí ó mú ilé Israẹli dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, mo ti búra nítorí wọn pé wọ́n gbọdọ̀ jìyà.

13 Wọn kò gbọdọ̀ dé ibi pẹpẹ mi láti ṣe iṣẹ́ alufaa, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ mi ati àwọn ohun mímọ́ jùlọ; ojú yóo tì wọ́n nítorí ohun ìríra tí wọ́n ṣe.

14 Sibẹsibẹ, n óo yàn wọ́n láti máa tọ́jú tẹmpili ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ ní ṣíṣe ninu rẹ̀.

Àwọn Alufaa

15 “Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16 Àwọn ni wọn óo máa wọ ibi mímọ́ mi, wọn óo máa lọ sí ibi tabili mi, tí wọn óo máa ṣiṣẹ́ iranṣẹ, wọn óo sì máa pa àṣẹ mi mọ́.

17 Bí wọ́n bá ti dé àwọn ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú, wọn yóo wọ aṣọ funfun. Wọn kò ní wọ ohunkohun tí a fi irun aguntan hun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ lẹ́nu ọ̀nà ati ninu gbọ̀ngàn inú.

18 Wọn yóo wé lawani tí a fi aṣọ funfun rán, wọn yóo sì wọ ṣòkòtò aṣọ funfun. Wọn kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń mú kí ooru mú eniyan di ara wọn ní àmùrè.

19 Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan ní gbọ̀ngàn ìta, wọn yóo bọ́ aṣọ tí wọ́n wọ̀ nígbà tí wọn ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sí àwọn yàrá mímọ́. Wọn yóo wọ aṣọ mìíràn kí wọn má baà sọ àwọn eniyan náà di mímọ́ nítorí ẹ̀wù wọn.

20 “Wọn kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn tabi kí wọn jẹ́ kí oko irun wọn gùn, wọn yóo máa gé díẹ̀díẹ̀ lára irun orí wọn ni.

21 Kò sí alufaa kan tí ó gbọdọ̀ mu ọtí waini nígbà tí ó bá wọ gbọ̀ngàn inú.

22 Wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tabi obinrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, àfi wundia tí kò tíì mọ ọkunrin láàrin àwọn eniyan Israẹli tabi opó tí ó jẹ́ aya alufaa.

23 “Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ àwọn eniyan mi láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn nǹkan mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ ati àwọn nǹkan lásán. Wọ́n sì gbọdọ̀ kọ́ wọn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan tí kò mọ́ ati àwọn nǹkan mímọ́.

24 Bí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onídàájọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí èmi gan-an yóo ti ṣe é. Wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn òfin ati ìlànà mi mọ́ lákòókò gbogbo àṣàyàn àjọ̀dún wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́.

25 “Wọn kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di aláìmọ́ nípa sísúnmọ́ òkú, ṣugbọn wọ́n lè sọ ara wọn di aláìmọ́ bí ó bá jẹ́ pé òkú náà jẹ́ ti baba wọn tabi ìyá wọn tabi ti ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin tabi ti arakunrin wọn tí kò tíì gbeyawo tabi arabinrin wọn tí kò tíì wọ ilé ọkọ.

26 Lẹ́yìn tí alufaa bá di aláìmọ́, yóo dúró fún ọjọ́ meje, lẹ́yìn náà yóo di mímọ́.

27 Ní ọjọ́ tí ó bá lọ sí ibi mímọ́, tí ó bá lọ sinu gbọ̀ngàn inú láti ṣiṣẹ́ iranṣẹ ní ibi mímọ́, ó gbọdọ̀ rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

28 “Wọn kò ní ní ilẹ̀ ìní nítorí èmi ni ìní wọn, ẹ kò ní pín ilẹ̀ fún wọn ní Israẹli, èmi ni ìpín wọn.

29 Àwọn ni wọn óo máa jẹ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àwọn ni wọ́n ni gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ ní Israẹli.

30 Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín.

31 Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀ tabi tí ẹranko burúkú bá pa, kì báà jẹ́ ẹyẹ tabi ẹranko.