Isikiẹli 48 BM

Pípín Ilẹ̀ Náà láàrin Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

1 Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan.

2 Ìpín ti Aṣeri yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Dani, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

3 Ìpín ti Nafutali yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Aṣeri, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

4 Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,

5 Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

6 Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

7 Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

Ìpín Pataki láàrin Ilẹ̀ Náà

8 Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Juda ni ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo wà. Ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12.5), òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà pẹlu ti àwọn ìpín yòókù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ibi mímọ́ yóo wà láàrin rẹ̀.

9 Òòró ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ (kilomita 10).

10 Èyí yóo jẹ́ ilẹ̀ fún ibi mímọ́ mi, níbẹ̀ sì ni ìpín ti àwọn alufaa yóo wà, yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ní ìhà àríwá, ní ìwọ̀ oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), ní ìlà oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), òòró rẹ̀ ní ìhà gúsù yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½). Ibi mímọ́ OLUWA yóo wà ní ààrin rẹ̀.

11 Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ.

12 Lọ́tọ̀ ni a óo fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn. Yóo jẹ́ ìpín tiwọn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ilẹ̀ mímọ́ jùlọ; yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ti àwọn ọmọ Lefi.

13 Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5).

14 Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni.

15 Èyí tí ó kù lára ilẹ̀ náà tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), tí òòró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), yóo wà fún lílò àwọn ará ìlú, fún ibùgbé ati ilẹ̀ tí ó yí ìlú ká. Láàrin rẹ̀ ni ìlú yóo wà.

16 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà yóo gùn ní ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), ati ti ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati ti àríwá ati ti gúsù.

17 Ilẹ̀ pápá yóo sì wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà, ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan yóo gùn ní igba ó lé aadọta (250) igbọnwọ (mita 125).

18 Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú.

19 Àwọn òṣìṣẹ́ ààrin ìlú tí wọ́n bá wá láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli ni yóo máa dá oko níbẹ̀.

20 Gbogbo ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½) ní òòró ati ìbú. Èyí ni àròpọ̀ ibi mímọ́ ati ilẹ̀ ti gbogbo ìlú náà.

21 Ilẹ̀ tí ó kù lápá ọ̀tún ati apá òsì ilẹ̀ mímọ́ náà, ati ti ìlú yóo jẹ́ ti ọba. Ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí ilẹ̀ mímọ́ pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ati ibi tí ilẹ̀ mímọ́ náà pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilẹ̀ mímọ́ ati tẹmpili mímọ́ yóo sì wà láàrin rẹ̀.

22 Ilẹ̀ àwọn ọmọ Lefi ati ilẹ̀ gbogbo ìlú yóo wà láàrin ilẹ̀ ọba. Ilẹ̀ ọba yóo wà láàrin ilẹ̀ Juda ati ti Bẹnjamini.

Ilẹ̀ Àwọn Ẹ̀yà Israẹli Yòókù

23 Ní ti àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Bẹnjamini yóo ní ìpín kan.

24 Ìpín ti Simeoni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Bẹnjamini, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

25 Ìpín kan tí Isakari ní yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Simeoni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

26 Ìpín kan ti Sebuluni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Isakari, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

27 Ìpín kan ti Gadi yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Sebuluni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

28 Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè Gadi ní ìhà gúsù, ààlà ilẹ̀ náà yóo lọ láti Tamari títí dé ibi àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí dé àwọn odò Ijipti, tí ó fi lọ dé Òkun Ńlá.

29 Ilẹ̀ tí ẹ óo pín láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli nìyí; bẹ́ẹ̀ sì ni ètò bí ẹ óo ṣe pín in fún olukuluku wọn, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu

30 Ìwọ̀nyí ni yóo jẹ́ ẹnubodè àbájáde ìlú náà. Apá ìhà àríwá tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta.

31 Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Reubẹni, ẹnubodè Juda ati ẹnubodè Lefi. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli ni a fi sọ àwọn ẹnu ọ̀nà ìlú.

32 Apá ìlà oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Josẹfu, ẹnubodè Bẹnjamini ati ẹnubodè Dani.

33 Apá ìhà gúsù tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Simeoni, ẹnubodè Isakari ati ẹnubodè Sebuluni.

34 Apá ìwọ̀ oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Gadi, ẹnubodè Aṣeri ati ẹnubodè Nafutali.

35 Àyíká ìlú náà yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) igbọnwọ (mita 9,000). Orúkọ ìlú náà yóo máa jẹ́, “OLUWA Ń Bẹ Níbí.”