Isikiẹli 33 BM

Ọlọrun Fi Isikiẹli Ṣe Aṣọ́de ní Israẹli

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, bá àwọn eniyan rẹ sọ̀rọ̀. Wí fún wọn pé bí mo bá jẹ́ kí ogun jà ní ilẹ̀ kan, tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá yan ọ̀kan ninu wọn, tí wọ́n fi ṣe olùṣọ́;

3 bí ó bá rí ogun tí ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ náà, tí ó bá fọn fèrè tí ó fi kìlọ̀ fún àwọn eniyan,

4 bí ẹnìkan bá gbọ́ ìró fèrè náà, ṣugbọn tí kò bá bìkítà fún ogun àgbọ́-tẹ́lẹ̀ yìí, bí ogun bá pa á orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.

5 Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

6 Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.

7 “Ọmọ eniyan, ìwọ ni mo yàn ní olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu mi, o níláti bá mi kìlọ̀ fún wọn.

8 Bí mo bá wí fún eniyan burúkú pé yóo kú, tí o kò sì kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, eniyan burúkú náà yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

9 Ṣugbọn bí ìwọ bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, tí kò sì yipada, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ ti gba ẹ̀mí ara tìrẹ là.

Ẹrù Ẹnìkọ̀ọ̀kan

10 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé mo gbọ́ ohun tí wọn ń sọ pé, ‘Àìdára wa ati ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí wa, a sì ń joró nítorí wọn; báwo ni a óo ṣe yè?’

11 Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú?

12 “Ìwọ ọmọ eniyan, wí fún àwọn eniyan rẹ pé, bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là, bẹ́ẹ̀ sì ni bí eniyan burúkú bá yí ìwà rẹ̀ pada, kò ní kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní yè nítorí òdodo rẹ̀.

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wí fún olódodo pé yóo yè, bí ó bá gbójú lé òdodo ara rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, n kò ní ranti ọ̀kankan ninu ìwà òdodo rẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

14 Bí mo bá sì wí fún eniyan burúkú pé dandan ni pé kí ó kú, bí ó bá yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́,

15 bí ó bá dá nǹkan tí ẹni tí ó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pada, tí ó sì dá gbogbo nǹkan tí ó jí pada, tí ó ń rìn ní ọ̀nà ìyè láì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè; kò ní kú.

16 N kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí o ti dá mọ́. Nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, yóo yè.

17 “Sibẹsibẹ, àwọn eniyan rẹ ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́,’ bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀nà tiwọn gan-an ni kò tọ́.

18 Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

19 Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́, yóo yè nítorí rere tí ó ṣe.

20 Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń wí pé, ‘ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ìwà olukuluku yín ni n óo fi dá a lẹ́jọ́.”

Ìròyìn Nípa Ìṣubú Jerusalẹmu

21 Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹwaa ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, ẹnìkan tí ó sá àsálà kúrò ní Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó ní, “Ogun ti kó Jerusalẹmu.”

22 Ẹ̀mí OLUWA ti bà lé mi ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ẹni tí ó sá àsálà náà dé, OLUWA sì ti là mí lóhùn kí ọkunrin náà tó dé ọ̀dọ̀ mi ní àárọ̀ ọjọ́ keji; n kò sì yadi mọ́.

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Eniyan náà

23 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

24 “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli tí ó ti di aṣálẹ̀ wọnyi, ń wí pé, ‘Ẹnìkan péré ni Abrahamu, bẹ́ẹ̀ ó sì gba ilẹ̀ yìí. Àwa pọ̀ ní tiwa, nítorí náà, a ti fi ilẹ̀ yìí fún wa, kí á gbà á ló kù.’

25 “Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín?

26 Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí?

27 “Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta.

28 N óo sọ ilẹ̀ yìí di ahoro ati aṣálẹ̀. Agbára tí ó ń gbéraga sí yóo dópin. Àwọn òkè Israẹli yóo di ahoro tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní gba ibẹ̀ kọjá.

29 Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro ati aṣálẹ̀, nítorí gbogbo ìwà ìríra tí wọ́n ti hù.

Àwọn Àbọ̀dé Ìran Wolii Náà

30 “Ní tìrẹ, ìwọ ọmọ eniyan, àwọn eniyan rẹ tí ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri ati lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé wọn, wọ́n ń wí fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.’

31 Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà.

32 Lójú wọn, o dàbí olóhùn iyọ̀ tí ń kọrin ìfẹ́, tí ó sì mọ ohun èlò orin lò dáradára. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é.

33 Ṣugbọn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, (bẹ́ẹ̀ yóo sì ṣẹ), wọn óo wá mọ̀ pé wolii kan wà láàrin wọn.”