Isikiẹli 39 BM

A Ṣẹgun Gogu

1 OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali.

2 N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli.

3 Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ.

4 Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú.

5 Ninu pápá tí ó tẹ́jú ni ẹ óo kú sí; èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

6 N óo rọ òjò iná lé Magogu lórí, ati àwọn tí wọn ń gbé láìléwu ní etí òkun, wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

7 N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ”

8 OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé.

9 Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n.

10 Fún ọdún meje yìí, ẹnìkan kò ní ṣẹ́ igi ìdáná lóko, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gé igi ninu igbó kí wọ́n tó dáná; ohun ìjà ogun ni wọn yóo máa fi dáná. Wọn yóo kó ẹrù àwọn tí wọ́n ti kó wọn lẹ́rù rí; wọn yóo fi ogun kó àwọn ìlú tí wọ́n ti fi ogun kó wọn rí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìsìnkú Gogu

11 OLUWA ní, “Tí ó bá di ìgbà náà, n óo fún Gogu ní ibi tí wọn yóo sin ín sí ní Israẹli, àní àfonífojì àwọn arìnrìnàjò tí ó wà ní ìlà oòrùn Òkun Iyọ̀. Yóo dínà mọ́ àwọn arìnrìnàjò nítorí níbẹ̀ ni a óo sin Gogu ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ sí. A óo sì máa pè é ní àfonífojì Hamoni Gogu.

12 Oṣù meje ni yóo gba àwọn ọmọ Israẹli láti sin òkú wọn, kí wọ́n baà lè fọ ilẹ̀ náà mọ́.

13 Gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ni yóo sin wọ́n, wọn óo sì gbayì ní ọjọ́ náà, nígbà tí mo bá fi ògo mi hàn. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

14 Lẹ́yìn oṣù meje wọn yóo yan àwọn kan tí wọn óo la ilẹ̀ náà já, tí wọn óo máa wá òkú tí ó bá kù nílẹ̀, tí wọn óo sì máa sin wọ́n kí wọ́n lè sọ ilẹ̀ náà di mímọ́.

15 Bí ẹnìkan ninu àwọn tí ń wá òkú kiri bá rí egungun eniyan níbìkan, yóo fi àmì sibẹ títí tí àwọn tí ń sin òkú yóo fi wá sin ín ní àfonífojì Hamoni Gogu.

16 Ìlú kan yóo wà níbẹ̀ tí yóo máa jẹ́ Hamoni. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe fọ ilẹ̀ náà mọ́.”

17 OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀.

18 Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani.

19 Ẹ óo jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó ní ibi àsè tí n óo sè fun yín.

20 Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ìràpadà Israẹli

21 “N óo fi ògo mi hàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn ni yóo sì rí irú ẹjọ́ tí mo dá wọn ati irú ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.

22 Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọ Israẹli óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

23 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli dá tí wọ́n fi di ẹni tí ó lọ sí ìgbèkùn, ati pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi ni mo ṣe dijú sí wọn, tí mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi idà pa wọ́n.

24 Bí àìmọ́ ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo fìyà jẹ wọ́n tó, mo sì gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn.”

25 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli n óo kó àwọn ọmọ Jakọbu pada láti oko ẹrú, n óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì jowú nítorí orúkọ mímọ́ mi.

26 Wọn yóo gbàgbé ìtìjú wọn ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọn hù sí mi, nígbà tí wọn bá ń gbé orí ilẹ̀ wọn láìléwu, tí kò sì sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.

27 Nígbà tí mo bá kó wọn pada láti inú oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè, tí mo kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n óo fi ara mi hàn bí ẹni mímọ́ lójú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.

28 Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, nítorí pé mo kó wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, mo sì tún kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn. N kò ní fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀ sí ààrin orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́.

29 N óo tú ẹ̀mí mi lé àwọn ọmọ Israẹli lórí, n ko ní gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”