Isikiẹli 27 BM

Orin Arò fún Ìlú Tire

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nípa ìlú Tire.

3 Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní:Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé,o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan!

4 Agbami òkun ni bodè rẹ.Àwọn tí wọ́n kọ́ ọ fi ẹwà jíǹkí rẹ.

5 Igi firi láti Seniri ni wọ́n fi ṣe gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ.Igi kedari láti Lẹbanoni ni wọ́n sì fi ṣe òpó ọkọ̀ rẹ.

6 Igi oaku láti Baṣani ni wọ́n fi ṣe ajẹ̀ rẹ̀Igi sipirẹsi láti erékùṣù Kipru ni wọ́n fi ṣe ilé rẹ.Wọ́n sì fi eyín erin bo inú rẹ̀.

7 Aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára láti ilẹ̀ Ijipti,ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹtí ó dàbí àsíá ọkọ̀ rẹ.Aṣọ aláró ati aṣọ àlàárì láti etíkun Eliṣani wọ́n fi ṣe ìbòrí rẹ.

8 Àwọn ará Sidoni ati Arifadi ni atukọ̀ rẹ.Àwọn ọlọ́gbọ́n láti ilẹ̀ Ṣemeri wà lọ́dọ̀ rẹ,àwọn ni wọ́n ń darí ọkọ̀ ojú omi rẹ.

9 Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ,àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹkí omi má baà wọnú rẹ̀.Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́nwà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà.

10 “Àwọn ará Pasia ati àwọn ará Ludi ati àwọn ará Puti wà láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ bí akọni. Wọ́n gbé asà ati àṣíborí wọn kọ́ sinu rẹ, wọ́n jẹ́ kí o gba ògo.

11 Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé.

12 “Àwọn ará Taṣiṣi ń bá ọ rajà nítorí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ: fadaka, irin, páànù ati òjé ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.

13 Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà.

14 Àwọn ará Beti Togama a máa kó ẹṣin, ati ẹṣin ogun, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

15 Àwọn ará Didani ń bá ọ ṣòwò, ọpọlọpọ etíkun ni ẹ tí ń tajà, wọ́n ń fi eyín erin ati igi Ẹboni ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

16 Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

17 Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

18 Àwọn ará Damasku bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye tí ò ń tà, wọ́n mú ọtí waini ati irun aguntan funfun wá láti Heliboni.

19 Àwọn ará Fedani ati Jafani láti Usali a máa wá fi ọtí waini pààrọ̀ ohun tí ò ń tà; wọn a kó àwọn nǹkan èlò irin wá, ati igi kasia.

20 Àwọn ará Dedani náà ń bá ọ ṣòwò, wọ́n ń kó aṣọ gàárì tí wọ́n fi ń gun ẹṣin wá.

21 Àwọn ará Arabia ati àwọn olóyè Kedari ni àwọn oníbàárà rẹ pataki, wọn a máa ra ọ̀dọ́ aguntan, àgbò, ati ewúrẹ́ lọ́wọ́ rẹ.

22 Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ.

23 Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò.

24 Wọ́n ń kó ojúlówó ẹ̀wù aṣọ aláwọ̀ aró wá tà fún ọ, ati aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ati ẹni tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, tí wọ́n fi ìko hun.

25 Àwọn ọkọ̀ Taṣiṣi ní ń bá ọ ru ọjà rẹ lọ ta.Ọjà kún inú rẹ,ẹrù rìn ọ́ mọ́lẹ̀ láàrin omi òkun.

26 Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun.Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun.

27 Gbogbo ọrọ̀ rẹ, ati gbogbo ọjà olówó iyebíye rẹ,àwọn tí ń tu ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń darí rẹ;àwọn tí ń fi ọ̀dà dí ihò ara ọkọ̀ rẹati àwọn tí ń bá ọ ṣòwò.Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ ati àwọn èrò tí ó wà ninu rẹ,ni yóo rì sí ààrin gbùngbùn òkun, ní ọjọ́ ìparun rẹ.

28 Gbogbo èbúté yóo mì tìtìnígbà tí àwọn tí wọn ń tọ́ ọkọ̀ rẹ bá kígbe.

29 Gbogbo àwọn atukọ̀ ni yóo jáde kúrò ninu ọkọ̀.Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ọkọ̀ati àwọn tí ń darí ọkọ̀yóo dúró ní èbúté.

30 Wọn óo gbé ohùn sókè sí ọ,wọn óo sun ẹkún kíkan kíkan.Wọn óo da erùpẹ̀ sórí wọn,wọn óo yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú.

31 Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ,wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí,wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ,inú wọn yóo sì bàjẹ́.

32 Bí wọ́n bá ti ń sọkún,wọn óo máa kọ orin arò nípa rẹ báyìí pé:‘Ìlú wo ló tíì parun bíi Tire, láàrin òkun?

33 Nígbà tí àwọn ọjà rẹ bá dé láti òkè òkun,ò ń tẹ́ ọpọlọpọ eniyan lọ́rùn.Ò ń fi ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹsọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34 Wàyí ò, omi òkun ti fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́,o ti rì sí ìsàlẹ̀ òkun.’Gbogbo àwọn ọjà rẹati àwọn tí ń wa ọkọ̀ rẹ ti rì pẹlu rẹ.

35 “Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ń gbé etí òkun nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àwọn ọba wọn ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀rù sì hàn ní ojú wọn.

36 Àwọn oníṣòwò orílẹ̀-èdè ayé ń pòṣé lé ọ lórí. Òpin burúkú dé bá ọ, o kò ní sí mọ́ títí lae.”