Isikiẹli 38 BM

Gogu Gẹ́gẹ́ Bí Ohun Èlò Ọlọrun

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀,

2 ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Gogu, ní ilẹ̀ Magogu; tí ó jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali,

3 kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí, pé OLUWA Ọlọrun ní, Mo lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí Meṣeki ati Tubali.

4 N óo yí ojú rẹ pada, n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì mú ọ jáde, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ, ati àwọn ati ẹṣin wọn, gbogbo wọn, tàwọn ti ihamọra wọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ní asà ati apata, tí wọ́n sì ń fi idà wọn.

5 Àwọn ará Pasia, ati àwọn ará Kuṣi, ati àwọn ará Puti wà pẹlu rẹ̀; gbogbo wọn, tàwọn ti apata ati àṣíborí wọn.

6 Gomeri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati Beti Togama láti òpin ilẹ̀ ìhà àríwá ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, wọ́n wà pẹlu rẹ̀.

7 Dira ogun, kí o sì wà ní ìmúrasílẹ̀, ìwọ ati gbogbo eniyan tí wọ́n pé yí ọ ká, kí o jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fún wọn.

8 Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu.

9 Ẹ óo gbéra, ẹ óo máa bọ̀ bí ìjì líle, ẹ óo dàbí ìkùukùu tí ó bo ilẹ̀, ìwọ ati gbogbo ọmọ ogun rẹ, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tí ó wà pẹlu rẹ.”

10 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ náà èròkerò yóo wá sí ọkàn rẹ,

11 o óo wí ninu ara rẹ pé, ‘N óo gbógun ti ilẹ̀ tí kò ní odi yìí; n óo kọlu àwọn tí wọ́n jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ wọn láìléwu, gbogbo wọn ń gbé ìlú tí kò ní odi, kò sì ní ìlẹ̀kùn, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn.’

12 N óo lọ kó wọn lẹ́rù, n óo sì kó ìkógun. N óo kọlu àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro nígbà kan rí, ṣugbọn tí àwọn eniyan ń gbé ibẹ̀ nisinsinyii, àwọn eniyan tí a ṣà jọ láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, ṣugbọn tí wọ́n ní mààlúù ati ohun ìní, tí wọ́n sì ń gbé ìkóríta ilẹ̀ ayé.

13 Ṣeba ati Dedani ati àwọn oníṣòwò Taṣiṣi, ati àwọn ìlú agbègbè wọn yóo bi ọ́ pé, ‘Ṣé o wá kó ìkógun ni, ṣé o kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ láti wá kó ẹrú, fadaka ati wúrà, ati mààlúù, ọrọ̀ ati ọpọlọpọ ìkógun?’ ”

14 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí pé, OLUWA Ọlọrun ní: “Ní ọjọ́ tí àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, bá ń gbé láìléwu, ìwọ óo gbéra ní ààyè rẹ

15 ní ọ̀nà jíjìn, ní ìhà àríwá, ìwọ ati ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn lórí ẹṣin, ọpọlọpọ eniyan, àní, àwọn ọmọ ogun.

16 O óo kọlu àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan mi, bí ìkùukùu tí ń ṣú bo ilẹ̀. Nígbà tí ó bá yà n óo mú kí o kọlu ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè mọ̀ mí nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ ìwọ Gogu fi bí ìwà mímọ́ mi ti rí hàn níṣojú wọn.

17 OLUWA ní: ṣé ìwọ ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ láti ẹnu àwọn wolii Israẹli, àwọn iranṣẹ mi, tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọpọlọpọ ọdún pé n óo mú ọ wá láti gbógun tì wọ́n?

Ìyà Tí Ọlọrun Fi Jẹ Gogu

18 “Ṣugbọn ní ọjọ́ tí Gogu bá gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, inú mi óo ru. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19 Pẹlu ìtara ati ìrúnú ni mo fi ń sọ pé ilẹ̀ Israẹli yóo mì tìtì ní ọjọ́ náà.

20 Àwọn ẹja inú omi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko inú igbó, gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ati gbogbo eniyan tí ó wà láyé yóo wárìrì. Àwọn òkè yóo wó lulẹ̀, àwọn òkè etí òkun yóo ṣubú sinu òkun. Gbogbo odi ìlú yóo sì wó lulẹ̀.

21 N óo dá oríṣìíríṣìí ẹ̀rù ba Gogu, lórí òkè mi, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo fa idà yọ sí ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22 N óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú ogun ṣe ìdájọ́ wọn. N óo rọ òjò yìnyín, iná, ati imí ọjọ́ lé òun, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan pupọ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lórí.

23 N óo fi títóbi mi ati ìwà mímọ́ mi hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”