Isikiẹli 29 BM

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Ijipti

1 Ní ọjọ́ kejila oṣù kẹwaa ọdún kẹwaa, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀;

2 Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Farao ọba Ijipti, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òun ati gbogbo àwọn ará Ijipti pé,

3 OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’

4 N óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì jẹ́ kí àwọn ẹja inú odò Naili so mọ́ ìpẹ́ rẹ; n óo sì fà ọ́ jáde kúrò ninu odò Naili rẹ pẹlu gbogbo àwọn ẹja inú odò rẹ tí wọn óo so mọ́ ọ lára.

5 N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ.

6 Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí pé ẹ fi ara yín ṣe ọ̀pá tí àwọn ọmọ Israẹli gbára lé; ṣugbọn ọ̀pá tí kò gbani dúró ni yín.

7 Nígbà tí wọ́n gba yín mú, dídá ni ẹ dá mọ́ wọn lọ́wọ́, tí ẹ ya wọ́n léjìká pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nígbà tí wọ́n gbára le yín, ẹ dá ẹ sì jẹ́ kí wọ́n dá lẹ́yìn.”

8 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Wò ó, n óo fi ogun jà yín, n óo sì pa yín run, ati eniyan ati ẹranko.

9 Ilẹ̀ Ijipti yóo di ahoro, yóo sì di aṣálẹ̀. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.“Nítorí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili, ara mi ni mo dá a fún,’

10 nítorí náà, mo lòdì sí ìwọ ati àwọn odò rẹ, n óo sì sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro ati aṣálẹ̀ patapata láti Migidoli dé Siene, títí dé ààlà Etiopia.

11 Eniyan tabi ẹranko kò ní gba ibẹ̀ kọjá, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ fún ogoji ọdún.

12 N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”

13 OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn ogoji ọdún, n óo kó àwọn ará Ijipti jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá fọ́n wọn ká sí.

14 N óo dá ire wọn pada, n óo kó wọn pada sí ilẹ̀ Patirosi, níbi tí a bí wọn sí. Wọn óo sì wà níbẹ̀ bí ìjọba tí kò lágbára.

15 Òun ni yóo rẹlẹ̀ jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kò ní lè gbé ara rẹ̀ ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo sọ wọ́n di kékeré tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè jọba lórí orílẹ̀-èdè kankan mọ́.

16 Ijipti kò ní tó gbójú lé fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Ijipti yóo máa rán wọn létí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, pé wọ́n ti wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Ijipti tẹ́lẹ̀ rí. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”

Nebukadinesari Yóo Ṣẹgun Ijipti

17 Ní ọjọ́ kinni, oṣù kinni, ọdún kẹtadinlọgbọn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

18 “Ìwọ ọmọ eniyan, Nebukadinesari ọba Babiloni mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Tire kíkankíkan. Wọ́n ru ẹrù títí orí gbogbo wọn pá, èjìká gbogbo wọn sì di egbò. Sibẹ òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò rí èrè kankan gbà ninu gbogbo wahala tí wọ́n ṣe ní Tire.

19 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo fi ilẹ̀ Ijipti lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó àwọn eniyan rẹ̀ lọ, yóo sì fi ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ṣe ìkógun, èyí ni yóo jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

20 Mo ti fún un ní ilẹ̀ Ijipti gẹ́gẹ́ bí èrè gbogbo wahala rẹ̀, nítorí pé èmi ni ó ṣiṣẹ́ fún. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

21 “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé alágbára kan dìde ní Israẹli, n óo mú kí ìwọ Isikiẹli ó sọ̀rọ̀ láàrin wọn. Nígbà náà, wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”