Isikiẹli 17 BM

Òwe Nípa Àwọn Ẹyẹ Idì ati Àjàrà

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.

3 Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan,

4 ó ṣẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ lórí, ó gbé e lọ sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò; ó fi sí ìlú àwọn tí ń ta ọjà.

5 Lẹ́yìn náà, ó mú ninu èso ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá, ní ẹ̀bá odò. Ó gbìn ín bí wọn tíí gbin igi wilo.

6 Igi yìí hù, ó dàbí àjàrà tí kò ga, ṣugbọn tí ó tàn kálẹ̀. Ẹ̀ka rẹ̀ nà sọ́dọ̀ idì yìí lókè, ṣugbọn gbòǹgbò rẹ̀ kò kúrò níbi tí ó wà. Ó di àjàrà, ó yọ ẹ̀ka, ó sì rúwé.

7 “Idì ńlá mìíràn tún wà, apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì pọ̀ lọpọlọpọ. Àjàrà yìí bá kọ orí gbòǹgbò ati ẹ̀ka rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ idì ńlá yìí, kí Idì náà lè máa bomi rin ín.

8 Idì yìí bá hú u níbi tí wọ́n gbìn ín sí, ó lọ gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá lẹ́bàá odò, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so èso, kí ó sì di àjàrà ńlá tí ó níyì.

9 “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò.

10 Nígbà tí wọ́n bá tún un gbìn ǹjẹ́ yóo yè? Ṣé kò ní gbẹ patapata nígbà tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóo gbẹ níbi tí wọ́n gbìn ín sí.”

Ìtumọ̀ Òwe Náà

11 Lẹ́yìn náà, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

12 “Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni.

13 Ó mú ọ̀kan ninu àwọn ìdílé ọba, ó bá a dá majẹmu, ó sì mú kí ó búra. Ó ti kọ́ kó gbogbo àwọn eniyan pataki pataki ilẹ̀ náà lọ,

14 kí ilẹ̀ náà lè di ìrẹ̀sílẹ̀, kí wọ́n má sì lè gbérí mọ́, ṣugbọn kí ilẹ̀ náà lè máa ní ìtẹ̀síwájú, níwọ̀n ìgbà tí ó bá pa majẹmu ọba Babiloni mọ́.

15 Ṣugbọn ọba Juda ṣọ̀tẹ̀ sí ti Babiloni, ó rán ikọ̀ lọ sí Ijipti pé kí wọ́n fún òun ní ẹṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Ǹjẹ́ yóo ní àṣeyọrí? Ṣé ẹni tí ń ṣé irú èyí lè bọ́? Ṣé ó lè yẹ majẹmu náà kí ó sì bọ́ ninu rẹ̀?

16 “Èmi OLUWA fi ara mi búra pé, ní ilẹ̀ Babiloni, ní ilẹ̀ ọba tí ó fi í sórí oyè ọba tí kò náání, tí ó sì da majẹmu rẹ̀, níbẹ̀ ni yóo kú sí.

17 Farao, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan rẹ̀, kò ní lè ràn án lọ́wọ́ nígbà ogun; nígbà tí ogun bá dótì í, tí wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ láti pa ọpọlọpọ eniyan.

18 Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.”

19 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo fi ara mi búra, n óo gbẹ̀san ìbúra mi tí kò náání lára rẹ̀, ati majẹmu mi tí ó dà.

20 N óo da àwọ̀n mi bò ó mọ́lẹ̀, pańpẹ́ mi yóo mú un, n óo sì mú un lọ sí Babiloni. Níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù sí mi.

21 Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.”

Ìlérí Ìrètí tí Ọlọrun Ṣe

22 OLUWA Ọlọrun ní:“Èmi fúnra mi ni n óo mú ọ̀kan ninu ẹ̀ka kan ní ṣóńṣó igi Kedari gíga,n óo ṣẹ́ ẹ̀ka kan láti orí rẹ̀,n óo gbìn ín sí orí òkè gíga fíofío.

23 Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí,kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so,kí ó sì di igi Kedari ńlá.Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀.Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀.

24 Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ péèmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré,mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá.Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ,má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”