Isikiẹli 3 BM

1 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ Eniyan, jẹ ohun tí a fún ọ; jẹ ìwé tí a ká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”

2 Mo bá la ẹnu, ó sì fún mi ní ìwé náà jẹ.

3 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, jẹ ìwé tí a ká, tí mo fún ọ yìí, kí o sì yó.” Mo bá jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.

4 Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn.

5 Kì í sá ṣe àwọn tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí ó ṣòro gbọ́, ni mo rán ọ sí, àwọn ọmọ ilé Israẹli ni.

6 N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ.

7 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn.

8 Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn.

9 Bí òkúta adamanti ṣe le ju òkúta akọ lọ ni mo ṣe mú kí orí rẹ le ju orí wọn lọ. Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí ojú wọn já ọ láyà, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”

10 Ó tún sọ fún mi, pé, “Ọmọ eniyan, fi etí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí n óo bá ọ sọ, kí o sì fi wọ́n sọ́kàn.

11 Lọ bá àwọn eniyan rẹ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, kí o sọ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ fún wọn; wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má sì gbọ́.”

12 Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.”

13 Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá.

14 Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára.

15 Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu.

OLUWA Yan Isikiẹli Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣọ́

16 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

17 “Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn.

18 Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

19 Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là.

20 “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.

21 Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.”

Isikiẹli yóo Ya Odi

22 Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

23 Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀.

24 Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ.

25 Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan.

26 N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.

27 Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”