Isikiẹli 45 BM

Ìpín OLUWA ní Orílẹ̀-Èdè Náà

1 “Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́.

2 Ẹ óo fi ààyè sílẹ̀ ninu ilẹ̀ yìí fún Tẹmpili mímọ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ, ẹ óo sì tún fi aadọta igbọnwọ ilẹ̀ sílẹ̀ yí i ká.

3 Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo wọn apá kan tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10), níbẹ̀ ni ilé mímọ́ yóo wà, yóo jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ.

4 Yóo jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà, yóo wà fún àwọn alufaa, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, tí wọ́n sì ń dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ iranṣẹ. Ibẹ̀ ni wọn yóo kọ́ ilé wọn sí, ibẹ̀ ni yóo sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ fún ibi mímọ́ mi.

5 Ẹ wọn ibòmíràn tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10). Ibẹ̀ ni yóo wà fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, ibẹ̀ ni wọn óo máa gbé.

6 “Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo ya apá kan sọ́tọ̀ tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), ilẹ̀ yìí yóo wà fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Ilẹ̀ Àwọn Ọba

7 “Ọba ni yóo ni ilẹ̀ tí ó yí ilẹ̀ mímọ́ náà ká nì ẹ̀gbẹ́ kinni keji, ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ninu ìlú náà, ní ìwọ̀ oòrùn ati ìlà oòrùn, yóo gùn tó ilẹ̀ ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, yóo bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìwọ̀ oòrùn yóo sì dé òpin ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.

8 Yóo jẹ́ ìpín ti ọba ní Israẹli. Àwọn ọba kò gbọdọ̀ ni àwọn eniyan mi lára mọ́, wọ́n gbọdọ̀ fi ilẹ̀ yòókù sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.”

Òfin Fún Àwọn Ọba

9 OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́.

10 “Òṣùnwọ̀n eefa ati ti bati tí ó péye ni kí ẹ máa lò.

11 “Òṣùnwọ̀n eefa ati òṣùnwọ̀n bati náà gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà, eefa ati bati yín gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n homeri kan. Òṣùnwọ̀n homeri ni ó gbọdọ̀ jẹ́ òṣùnwọ̀n tí ẹ óo máa fi ṣiṣẹ́.

12 “Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli.

13 “Ohun tí ẹ óo máa fi rúbọ sí OLUWA nìwọ̀nyí: ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri ọkà yín kọ̀ọ̀kan, ati ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri alikama yín kọ̀ọ̀kan.

14 Ìwọ̀n òróró gbọdọ̀ péye gẹ́gẹ́ bí ìlànà; ìdámẹ́wàá ìwọ̀n bati mẹ́wàá ni òṣùnwọ̀n bati kan ninu òṣùnwọ̀n kori kọ̀ọ̀kan òṣùnwọ̀n kori gẹ́gẹ́ bíi ti homeri.

15 Ẹ níláti ya aguntan kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ ninu agbo ẹran kọ̀ọ̀kan tí ó tó igba ẹran, ninu àwọn agbo ẹran ìdílé Israẹli. Ẹ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16 “Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ kó àwọn nǹkan ìrúbọ náà fún àwọn ọba Israẹli.

17 Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

Àwọn Àjọ̀dún

18 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ẹ pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ẹ fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ibi mímọ́.

19 Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi sí ara òpó ìlẹ̀kùn tẹmpili, ati orígun mẹrẹẹrin pẹpẹ ati òpó ìlẹ̀kùn àbáwọlé gbọ̀ngàn ààrin ilé.

20 Bákan náà ni ẹ gbọdọ̀ ṣe ní ọjọ́ keje oṣù láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀; kí ẹ lè ṣe ètùtù fún tẹmpili.

21 “Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni, ẹ gbọdọ̀ ṣe ọdún Àjọ Ìrékọjá, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ óo máa jẹ fún ọjọ́ meje.

22 Ní ọjọ́ náà ọba yóo pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn ará ìlú.

23 Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

24 Fún ẹbọ ohun jíjẹ yóo pèsè òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati òṣùnwọ̀n hini òróró kọ̀ọ̀kan fún òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.

25 “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje, tíí ṣe ọjọ́ keje àjọ̀dún náà, yóo pèsè irú ẹbọ kan náà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró.”