Isikiẹli 21 BM

Idà OLUWA

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli.

3 Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú.

4 N óo pa àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú tí ó wà ninu rẹ run, nítorí náà, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo eniyan láti ìhà gúsù títí dé ìhà àríwá.

5 Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo fa idà mi yọ, n kò sì ní dá a pada sinu àkọ̀ mọ́.’

6 “Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn.

7 Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

8 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

9 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní:Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa.

10 A ti pọ́n ọn láti fi paniyan;a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná.Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá;nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi.

11 Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á,kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́.

12 Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún,nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí;ati àwọn olórí ní Israẹli.Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi.Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu.

13 Mò ń dán àwọn eniyan mi wò,bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada,gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn,Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

14 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí.

15 Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á.

16 Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí.

17 Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Idà Ọba Babiloni

18 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

19 “Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú.

20 La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká.

21 Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran.

22 Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í.

23 Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ.

24 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25 “Ìwọ olórí Israẹli, aláìmọ́ ati ẹni ibi, ọjọ́ rẹ pé; àkókò ìjìyà ìkẹyìn rẹ sì ti tó.

26 Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀.

27 Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́.

Idà ati Àwọn Ará Amoni

28 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí:‘A ti fa idà yọ, láti paniyan.A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná.

29 Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn.

30 “ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́.

31 N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun.

32 O óo di nǹkan ìdáná, lórí ilẹ̀ yín ni a óo pa yín sí, ẹ óo sì di ẹni ìgbàgbé, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”