Isikiẹli 37 BM

Àfonífojì Tí ó kún fún Egungun Gbígbẹ

1 Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi, ẹ̀mí rẹ̀ sì gbé mi wá sinu àfonífojì tí ó kún fún egungun.

2 Ó mú mi la ààrin wọn kọjá; àwọn egungun náà pọ̀ gan-an ninu àfonífojì náà; wọ́n sì ti gbẹ.

3 OLUWA bá bi mí léèrè, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn egungun wọnyi lè tún jí?”Mo bá dáhùn, mo ní, “OLUWA, ìwọ nìkan ni o mọ̀.”

4 Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’.

5 Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè.

6 N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

7 Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Bí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí so mọ́ ara wọn; egungun ń so mọ́ egungun.

8 Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, iṣan ti dé ara wọn, ẹran ti bo iṣan, awọ ara sì ti bò wọ́n, ṣugbọn kò tíì sí èémí ninu wọn.

9 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún èémí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Wá, ìwọ èémí láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé, kí o fẹ́ sinu àwọn òkú wọnyi, kí wọ́n di alààyè.’ ”

10 Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró!

11 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọ Israẹli ni àwọn egungun wọnyi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ; kò sí ìrètí fún wa mọ́, a ti pa wá run patapata.’

12 Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli.

13 Ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ṣí ibojì yín, tí mo sì gbe yín dìde, ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

14 N óo fi ẹ̀mí mi sinu yín, ẹ óo sì tún wà láàyè; n óo sì mu yín wá sí ilẹ̀ yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀, tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

Juda ati Israẹli Yóo Di Orílẹ̀-Èdè Kan

15 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16 “Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’

17 Fi ẹnu wọn ko ara wọn, kí wọ́n di igi kan lọ́wọ́ rẹ.

18 Bí àwọn eniyan rẹ bá bi ọ́ pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí ò ń ṣe yìí?

19 Wí fún wọn pé èmi OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo mú igi Josẹfu ati àwọn ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, n óo fi ẹnu rẹ̀ ko ẹnu igi Juda; n óo sọ wọ́n di igi kan, wọn yóo sì di ọ̀kan lọ́wọ́ mi.’

20 “Mú àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára lọ́wọ́, lójú wọn,

21 kí o sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ wò ó! N óo kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà, n óo kó wọn jọ láti ibi gbogbo wá sí ilẹ̀ wọn.

22 N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́.

23 Wọn kò ní fi ìbọ̀rìṣà kankan, tabi ìwà ìríra kankan tabi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, sọ ara wọn di aláìmọ́ mọ́. N óo gbà wọ́n ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìfàsẹ́yìn tí wọ́n ti dá. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

24 Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo jọba lórí wọn; gbogbo wọn óo ní olùṣọ́ kan. Wọn óo máa pa òfin mi mọ́, wọn óo sì máa fi tọkàntọkàn rìn ní ìlànà mi.

25 Wọn óo máa gbé ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín gbé. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn ati àwọn ọmọ ọmọ wọn yóo máa gbé ibẹ̀ títí lae. Dafidi iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba wọn títí lae.

26 N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae.

27 N óo kọ́ ibùgbé mi sí ààrin wọn, n óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.

28 Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ya Israẹli sọ́tọ̀, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà láàrin wọn títí lae.’ ”